September 20, 2024

 



 

 

Akojanu-Ile Igbimọ Asofin Ọyọ, Gbenga Oyekọla Da’ba Pe O Se Pataki Lati ro Awọn Ijọba Ibilẹ L’agbara Lori ọna Ẹsẹ Kuku Ati Igberiko

Alakojanu-Ile Igbimọ Asofin Ipinlẹ Ọyọ, ti o n soju Ijoba Ibilẹ Atiba, Asofin Gbenga Joseph Oyekọla ti Da’ba Ofin pe, o se pataki lati rọ awọn Ijọba Ibilẹ L’agbara lati pari sise atunse awọn oju opopona ni ẹsẹ kuku ati ọna Igberiko ni agbegbe koowa won ni Ipinlẹ Ọyọ.

Nigba to n sagbekale aba ohun, ni Ile Igbimọ Asofin Ipinle Ọyọ Lana, Asofin Gbenga Oyekọla Woye àwọn ipò tí kò bá ojumu tí awọn òpópóna ẹsẹkūku ati igberiko wá loni, bí ótile jẹ pé oriyin to sí ijọba Ipinlẹ Ọyọ lábẹ idarí ọlọlajulọ Onímọ Ẹrọ Seyi Mákindé, lórí idawọlé àti àseyọri awọn opopóna ijoba ipinle, Sugbọn ó se pataki kí á woye awọn òpopónà tí a ó tọ kí á tó de orí àwọn ọnà tí ljọba Ipinle se wọn yi.

Adari ile, ẹyin ẹlẹgbẹmi, lara ojúse ljọba Ibilẹ gẹgẹ bii ljọba tí o súnmọ ara ilu julọ ní láti pèsè àti síse atúnse awon opopona ẹsẹkuku ati īgberiko.

Eléyi wa ni ibámu pẹlú Iwé Ófin Orilèède yí ní ipín kẹrin (fourth schedule) ní abala ‘P’ sí nóm bà kìní (1)(f) eýi tí ó pa ljọba Ibilẹ làse láti la opopóna ati sisę amójutó àwọn òpópóna tí ó wa ni ikawọ wọn (Construction and Maintenance of Roads).

Ẹwẹ, Oyekọla túbọ woye pé kika wo ro awon Ijọba ibilẹ si ojuse won wonyi wa lára ohun tí o se okufa ijakulẹ tàbí owọn gogo oúnjẹ eyí tí ará ilú ńkojú lọwọlọwọ, ẹyin ẹlẹgbẹmi akóbá ńlá ni ipò gárí gádá tí àwọn òpópóna igberiko wa nse fún ijageere ọkọ láti kó awọn ikóore láti oko wá sí ọja nibití ara ilú yío ti rí rà, ìwọnba tí ó ba jaja de ọja ni won yio gbówó geege gun lóri látări wíwón tí owó oko láti kó ère oko dé oja gbé lórí gege. Eyi si ndakun inira tí ará ilu ńkojú lásiko ipènijà ọrọ ajé tí a wà yĩ.

O tun Kiyesi pé, ijọba Ibilẹ ni isakóso tí ó kangun sí ará ilú julọ, èyí tí awọn oludibo sì ní Iretí kíkún nínú rẹ pé yíò bu omi tútù sí ibi tí bata ti í ta wón ní ẹsẹ, pípọ ojúse tí ará ilú ńretí pé ljọba Ibilẹ yio gbájú mọ lố tì wà ní ipò ọmọ orukan, eyí tí kò sí ẹni tó rí gẹgẹ bí ojú se wọn làti samójúto rẹ.

Akojanu-Ile Igbimọ Asofin, tubọ kiyesi pe siwaju asiko yí awon isé takun takun ní ẹsẹkuku tí awon ljọba Ibilẹ má nse ni kiïse fi ọwọ rọ sẹyìn nínú síse odiwon tabi igbelewon isakoso kan si omíran. Siwaju asiko yi, ọpọlọpọ awọn opopoña to wa ni ikawo ljoba Ibilẹ ni ó ma nrí atunse lore koore páapá julọ awon oju opopona igberiko.

“Eyi si je ona kan pato ti ljoba ngba lati sọ awon to ngbe ni igberiko ati awon to wa ni igboro pọ fun idokowo ati irufẹ awon ohun amú ayé derọ míran”.

Akojanu-Ile túbọ Gbarata pe, lái se pé ljọba Ipinle Ọyo lábẹ Onímọ Ẹrọ Seýi Mákindé rọ awon ljọba ībilẹ lágbára láti parí síse atunse awon opopona esekuku ati ní pataki julọ awọn opopona ti o so igberiko mó igboro, paapa bí asiko ojo se fi ese lelẹ bayi, ńse ni awon ojú opopona yi yiò má bajẹ si tí yio sì ma lekun isoro igbokegbodo abi lilọ bibọ oko tí o sile se akobá ńlá fuń kiko ere oko wasi ọja bákanná ni o le yọrí si ọwọn gogo ounjẹ.

Lẹyin eyi ni Alakojanu-Ile ati Igbimọ Asofin Ipinlẹ Ọyọ pinu lati ro Ẹka Alásẹ ljọba pe;

Ẹka Alasẹ nipasë llé Isẹ ljọba to nri sí ọrọ ljọba Ibilẹ ati Oye Jijẹ (Ministry of Local Government and Chieftaincy Matters) ní Ipinlẹ Ọyọ láti seto ríró Ijọba Ibilẹ lagbara isuna owo latii pari sise atúnse awon opopona ẹsẹkuku papa julọ awon opopona igberiko.

Bakanna lati se igbesẹ bi lila ati sise atunse opopona igberiko yió se wá nínu awọn èto to le waju nínu Aba Isuna awon ljọba Ibilẹ, fun odun yí (2024).

Ki Igbimo lle tó o wà fun ọrọ ljọba Ibilẹ, Oye Jíjẹ ati Idalọla Ipinlẹ (Committee On Local Government, Chieftaincy Matters and State Honours) fikun-lukun pẹlú ilé isẹ to ri si ọrọ ljọba Ibilẹ ati Oye Jijẹ (Ministry of Local Government And Chieftaincy Matters) lori síse amuse ifẹnuko llé pe ki Eka Alásẹ o rọ awon ljọba Ibilẹ lagbara ki won o le pari sise atunse awon opopóna ẹsẹkuku ati igberiko.

Share this via

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *