Alakojanu-Ile Igbimo Asofin Ipinlẹ Ọyọ, ti o n soju Ijoba Ibilẹ Atiba, Asofin Gbenga Joseph Oyekola ti Da’ba Ofin pe, o se pataki lati gbe Ise Agbẹ Larugẹ, lati dena Ebi O Pa ‘Gba Fowo Meke ni Ipinlẹ Ọyọ.
Nigba to n sagbekale aba ohun, ni Ile Igbimo Asofin Ipinle Oyo Lana, Asofin Gbenga Oyekola Woye pe bi oja ounjẹ se n gbowo’ari ni isẹju isẹju läkoko yi, ti a ko ba gbagbe Aare Orileede yi Aare Hämed Tinubu kede nkan o fi araro ni eka onje ni orilede, eyi ti o fi pase ki won o si ibudo ikounje pamo si, ki o le bu tutu si isoro ebi opa ‘gba fowo meke lawujo Naijiria.
Ẹwẹ, Oyekola Kiyesi pe ailaso lorun Paaka o to apero fun omo Eriwo, ise agbe ti n wokun la ni Ipinle yi, ti a ba woye awon isoro ti n koju awon agbe bii, fifi eran je oko, pipa awon agbe sinu oko, owo bantu ti ise ak pe fun ni akoko yi ati beebe in Iwadi fi han pe ni odun meji sẹyin awon agbẹ npa oko sare kan ni egberur medogun naira, ni odun ti o koja owo na fe fere odi ogun egberun naira, ni asiko yi ora tun ti beyin yo nigbati awon egbe oni katakata (Tractor workers) ti pinu lati gbe owo won soke si ogbon egberun ole marun naira, (#35,000.00k).
Eleyin pe akiyesi wa si owo gege ti a o ma fi ra awon ounje ti ko ba si igbese kanmonkia.
Siwajú asikò ví ni awon odun die seyin, ijoba ipinlẹ Oyo ti seto yiya awon agbe oni katakara ni Owo láti fi pa oko won pelú owo taseré. Wón se ibudó iya katakara si awon ekun kookan tí ani ni Ipinlệ Ọyo, ní Igbana eléyí je okan ninu Iranwo ti ijoba se fun awon agbe tí ó sì té won lorun yato sí awon èta tí óle má kan awon agbe to wa ni oko lara.
Fun apeere èto owoya tí ljoba Apapo ati ti Ipinte gbe kale fun awon agbe ní o nira die lati ri gba fún agbe, tía bắ wo lana tí o wa lati gba owo ví, pupo awon torí owo vó ví yi gba ni awon agbe tí wón de tai morùn tí won joko sínu yara oloyé.
Oyekola tunbo kiyesi pe, ni abala awon olutaja, aisi igbimo ti on se amojuto idiyele lori oja ti ta ti fun awon onisowo ni aanfani lati ma ta awon oja won ni iye ti o ba wu won.
Eyi ti o tubo ndi eru to wuwo kun isoro eyi to ti gba Orilede kan. Sise akopamo ounje lati odo awon onisowo naa ko kere ninu isoro ti awujo nkoju.
Alakojanu-Ile tubo gbarata pe, isoro owon gogo oúnje ti so opolopò báále di eni tó rí i ìdaji jade tí yió sì wolé ní aajin dudu latarí pé kò sí ona abayo lati fun ebi re ni jije ati miimu. Eleyi ko sèyin bí awon ohun ti enu nje se n gbowo lórí. Awon ohun jije bi isu, Iresi, epo pupa, ata, tomato, elùbo, agbado gaari ati beebé lò. Adarí ilé, osisé ti o wa ni ipele owo osu kejo le dása mo lounje nie pelu ibi tí nkan won de, gbogbo onise owo ni kò mo ona abayo lati mó fi bo ebi rè, lai da owo bo enu. Adari ile ko si ohun ti won pe ni iyan to ju eyi ti onba wa finra ní awujo wa loni.
O Woye pe, sise itoju ati iranwo ododo fun awon agbe je ona pataki láti bu omi tutti si isoro owon gogo ounje lásiko yi ti se pataki fun ijoba ni gbogbo (cal sectors) ęka lati ko ibi ara si ise agbe laruge yato fun ariwo lásan lori ero ayelu jara (internet). Orilede kan ko le kése jari ninu eto oro aje ti irufe oriléède na ba rogbokun sori kiko ounje wole lati oke-okun.
O tun Gbarata pé, iroyin fi tówa létí pé ní òsẽ bí meji seyin, Gómina Ipinle Anambra Omowe Soludo latari owo igbeni nigbuwó tí ó rí gba lati ljoba Apapo rá igba merin (800) ero apako (tractor) èyí tí won pín fún àwon agbe lofe, eleyi wayé latări ki oúnje ole sun wốn bồ lópo yanturu, sé tí ebi bá kúrò nínú isẹ, isẹ buse.
Oyekola tun woye pe ijoba Ipinle Oyo labe Ololajulo wa, Gomina Seyi Makinde ti te pepe orisirisi eto k’ebi ma palu ninu ijoba re, ninu eyi ti a ti ri agbekale ajo “SAFER” sise igbe laruge Ibudo awon agbe si ti igbalode (Farm Estates). Bakanna ni eto eyawo fun awon agbę naa ko gbeyin.
Sugbon pelu gbogbo eto yi onje tubo ngbowo lori. Fun apere, apo iresi kan ni osu die seyin koju egberun lona ogbon ole marun naira lo (N35,000), loni apo iręsi ti le ni ogorin egberun naira (over eighty thousand N80,000.00k)
Leyin eyi ni Alakojanu-Ile ati Igbimo Asofin Ipinle Oyo pinu lati ro Èka Aláse ljoba pe;
Ni ipase lle Ise Agbę ati Idagbasoke Igberiko (Ministry of Agriculture and Rural Development) lati se dapada awon ibudo iya irinse agbe bi katakara, ero ifinko ati beebelo si awon ekun idibo wa ni ipinle oyo bil Oyo, Ogbomoso, Oke-Ogun, Ibarapa, ati Ibadan.
Bakanna ni ipase lle Ise to n risi eto Okowo, Karakata ati Alajeseku (Ministry of Trade, Investments and Cooperatives) se agbekale Igbimo ti yio ma risi idiyele oja (Price Regulatory Board) ni Ipinle Oyo;
Lati se iranlowo ajile (fertilizers) ati awon irúguin bí a se bú sí asiko ogbin. Nípasę ilé-isé tó n rísí Ètò Oko-Owò, Kárakátà ati Alájeséku (Ministry of Trade, Investments and Cooperatives) gbé gbogbo gbésè tó se lábé ofin láti dèna kiko Oja ońję pamó lóna àitó. Bí ebi bá kúrò nínu ise, sé bùse.