Asofin Ariwa Ibadan Keji, Onarebu Adebayo Babajide Gabriel ti Rawo Ebe Si Gómìnà Ìpínlè Òyó, Ololajulo Onimo Ero Oluseyi Abiodun Makinde lórí Ipò tí Afárá Adógba, Ïyànà Soosi Ati Afárá Òpópónà Ajagun Fèhìntì Adewumi Salawu wa ni Àdúgbò Agbowó.
Nigba to n se agbekale aba Irawo Ebe ohun, ni Ojo ru, ni Ile Igbimọ Asofin Ipinle Ọyọ, Asofin Adebayo Babajide Gabriel, ke gbajare pe afara Adogba ati Adewumi yii je ona pataki ti o so opolopo adugbo ati opopona agbegbe yii papo, igbese kiakia se pataki ti a o ba fe ki afara mejeji yii di omiyale si gbogbo Àdúgbò wonyi.
Asofin Adebayo Babajide tunbo woye pe, awon afara mejeji yii ti baje patapata, eyi ti o mu ki lilo bibo ati lilo geere oko je inira fun awon olugbe agbegbe mejeji yii, ti o si ti ko ipaya si okan awon olugbe agbegbe naa, nitori ipo ewu ti awon afara mejeji yii wa.
O wa pe akiyesi alaga to nri si opopona Ijoba Ìpínlè (OYSROMA) si ipo ewu ti awon afara yii wa, ti ara adugbo ati Alaga OYSROMA si se abewo si awon afara mejeji yii ti Alaga si se adehun pe laipe ljoba yi ose eto amaye rorun ati atunse lori afara yi ki o to di pe yio baje patapata, lati bi osu mesan seyin, sugbon ti a ko ri igbese Kankan.
Babajide tun se Akiyesi pe, lotito ljoba nse ise ribiribi lori oju ona wa gbogbo ni Ipinle Oyo, a si ki gomina wa Ololajulo Onimo Ero Seyi Makinde fun ise ribiribi ti won nse papajulo ni agbegbe temi gan papa, lati ile ljoba, Bodija, U.I, Mokola titi de Orita Sango, mo ki yin eku ise ribiribi ti e nse. Sugbon o se Pataki ki e bawa fi oju wo awon aarin gbungbun ilu toripe gbogbo awon ona wonyi lo ti baje tan patapata.
O tunbo kiyesi pe, pataki awon afara mejeji yii lori oro aje agbegbe naa, ko se foju fo rara, ni eyi ti o si ti nse akoba fun ilosiwaju oro aje agbegbe na, nitori fun apeere, afara Ajagun Fehinti Adewumi Salawu yi ni o so Agbowo ati opopona morose Oojo, lati bodija Iso Pako titi de Bodija Oja papo, ti afara adogba si so awon agbegbe ibile Lagelu ati Egbeda papo, ti awon afara mejeji yi ba baje tan yio pagi dina eto oro aje ati lilo bibo awon ara agbegbe yii patapata.
“Adari Ile, eyin elegbe mii, Ipò tí awon olugbe Àdúgbò wonyi wa, ko dara to”.
Leyin eyi ni Asòfin Adebayo Babajide pinu lati ro eka alase Ijoba pe;
Ki Alaga OYSROMA ati awon igbimo won pada lose abewo si awon afara mejeji yii.
Ki Ijoba Ìpínlè Òyó se igbese kiakia nipa atunse awon afara mejeji yii.
Ki Gomina Ìpínlè Òyó, Ololajulo Onimo Ero Seyi Makinde ati awon igbimo won se igbese kiakia nipa atunse awon oju ona aarin gbungbun ilu wonyi.
Ki awon ijoba ibile papa fi owo sowo po pelu ijoba ipinle lori akitiyan won ki won si beere atunse lori awon oju ona gbogbo wonyi.