December 23, 2024
IMG-20241016-WA0358

 



 

 



Asofin to n soju ekun Idibo Ila-Oorun Ibadan ni Ipinle Òyó (Ibadan North Constituency II), Hon. Adebayo Babajide Gabriel ti Keji Àbá Alakojanu-Ile Igbimọ Asofin Ipinlẹ Ọyọ, ti o n soju Ijoba Ibilẹ Atiba, Asofin Gbenga Joseph Oyekọla Lori Igbajare lati Da’ba Ofin pe, o se pataki Lati Dekun Dida Erupe, Okuta Yoyo Tabi Biriki Pelu Eroja Ikole Miran Si Oju-Opopona Ipinle Òyó.

Nigba to n sikeji agbekale aba ofin ohun, ni Ile Igbimọ Asofin Ipinle Ọyọ Lana, Asofin Adebayo Babajide Gabriel kiyesi wipe o se Pataki Lati wa iderun ba ohun ti o le mu eniyan lo soorun lai tojo, lori Iwa buruku ti awon oloko ako yoyo n wu, latari jija erupe ati awon eroja ikole miran si oju opopona laibikita awon ewu tabi ijamba ti irufe eroja ikole bee lese fun ara adugbo tabi olurekoja ni Ipinle Òyó.

Babajide tesiwaju Lori Oro re pe asa jija ohun eloikole bii biriki, yanrin tabi erupe, yoyo si oju opopona ti di baraku fun awon awako ako yoyo ati awon onibara won julo pupo, ti ko si ye kio ri be ni Ilu to ni Ofin ati Asa paapaa julo ni Ipinle Òyó.

Ewe, Iwa buruku awon Awako ako yoyo le fo Oju eniyan ti irufe Oko naa barekoja Lori titi pelu eniyan to ba gun tatapupu/Okada ni asiko ti Iji ba fe ategun lai ro ti tele.

Opo eniyan ni kiko erupe soju opopona ti ran lo sorun ti opo si ti di alaabo-ara latari aibikita awon ako yoyo won yii.

O wa ro Adari lle, Lati woye eyi ti ogaju ninu isoro iwa aibikita yi ni pinpin ti awon eroja ikole won yii ma n pin oju opopona si meji ti yio si fa sunkere gbakere oko ni oju popo ti eleyi naa si ni awon akoba ti o le se fun awon ti nlo, ti o n bo.

Asofin Adebayo Babajide ke gbajare si ile ise tonrisi oro ayikaa ati oun alumoni inu omi (Ministry of environment, Ecology and water resources) lati ma fi owo ofin mu enikeni ti o ba da erupe, okuta, yoyo, oparun ati beebeelo si oju opopona ti ile si su ba nibe pelu owo itanran ti o gbopon.

O tunbo sikeji erongba Akojanu-Ile Igbimo Asòfin Òyó, Oyekola lati ro gbogbo eka ile ise ijoba ti won nise pelu oju opopona lati fi owo tonipon mu enikeni ti o ba nja eroja ikole si oju opopona ti o nlo ju ojo kan lo.

Share this via

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *