Alakojanu-Ile Igbimọ Asofin Ipinlẹ Ọyọ, ti o n soju Ijoba Ibilẹ Atiba, Asofin Gbenga Joseph Oyekọla ke gbajare lati Da’ba Ofin pe, o se pataki Lati Dekun Dida Erupe, Okuta Yoyo Tabi Biriki Pelu Eroja Ikole Miran Si Oju-Opopona Ipinle Òyó.
Nigba to n sagbekale aba ohun, ni Ile Igbimọ Asofin Ipinle Ọyọ Lana, Asofin Gbenga Oyekọla Kiyesi iwa ailakakun eyi ti o gaga ara lati odo awon oloko ako yoyo latari jija erupe ati awon eroja ikole miran si oju opopona laibikita awon ewu tabi ijamba ti irufe eroja ikole bee lese fun ara adugbo tabi olurekoja. Se awon agba bo won ni ti ara ile eni banje kokoro mo obi, ti a ko ba wifun huruhere re ko ni je ka ri orun sun lale.
Adari ile, eyin elegbemi, asa jija ohun eloikole bii biriki, yanrin tabi erupe, yoyo si oju opopona ti di baraku fun awon awako ako yoyo ati awon onibara won.
Ewe, Akojanu-Ile tunbo kiyesi pe, opolopo ijamba ni kiko yoyo si oju opopona ti se fun awon oloko tabi awon ti won ngun tatapupu/okada latari bi won se nkolu awon erupe yi ni airotele nigbati ile ba tisu tabi ni afemoju ti o yę ko ti la daradara.
Opo eniyan ni kiko erupe soju opopona ti ran lo sorun ti opo si ti di alaabo-ara latari aibikita awon ako yoyo won yii.
O tun woye pee, yato si isoro tabi akoba ti dida yoyo si oju opopona nse fun opo eniyan, nise ni iwa yi tun je okan gbogi ti o nba awon opopona wa je, atipe nse ni oun so ijoba di apa lori owo ana tuna nipase titun awon ojusan omi ti ijoba la si egbe opopona latari wiwo ti ojo man wo awon erupe ti won da si oju opopona wonyi si inu ojusan omi (drainage) ti yi o si pagi dina jija geere sisan omi papa julo nigbati ojo ban ro.
Asòfin Oyekola tunbo woye pe, lara akoba ti eleyi tun le mu lowo ni biba oju opopona je latari pe ti omi o ba ri ona koja ni ojusan ti won lafun, omi yio pada si ori opopona eyi ti o si ma nba opopona ję lai tojo rara.
“Adari lle, eyi ti ogaju ninu isoro iwa aibikita yi ni pinpin ti awon eroja ikole won yii ma n pin oju opopona si meji ti yio si fa sunkere gbakere oko ni oju popo ti eleyi naa si ni awon akoba ti o le se fun awon ti nlo oju opopona”.
Akojanu-Ile tun bo Gbarata pe, lai sepe ljoba fi owo ofin mu enikeni ti o ba da awon eroja ikole si oju opopona ju wakati marun lo ati pe ilę ko gbodo su ba irufę eroja naa nibe awon akoba ti oun suyo latari iwuwasi wonyi koni ye waye bakanna ijoba ko ni ye na owo anatunna lori atunse oju opopona kaakiri Ipinle Oyo.
Lẹyin eyi ni Alakojanu-Ile ati Igbimọ Asofin Ipinlẹ Ọyọ pinu lati ro eka alase ijoba pe;
Ni ipasę ile ise tonrisi oro ayikaa ati oun alumoni inu omi (Ministry of environment, Ecology and water resources) lati ma fi owo ofin mu enikeni ti o ba da erupe, okuta, yoyo, oparun ati beebeelo si oju opopona ti ile si su ba nibe pelu owo itanran ti o gbopon.
Tubu ro gbogbo eka ile ise ijoba ti won nise pelu oju opopona lati fi owo tonipon mu enikeni ti o ba nja eroja ikole si oju opopona ti o nlo ju ojo kan lo.